24/04/2026
ABẸWO IKUBABAYEYE ATI AYABA ALAAFIN SILU JEBBA ATI SHAO NI IPINLẸ KWARA.
Ninu Itan
Jebba ati Shao jẹ ara Ilẹ Yoruba labẹ Alaafin ẹkun osi Ọyọ lo wa.
Ọmọ Alaafin ni awọn mejeji Jẹbba jẹ ilu alade isẹnbaye ti ọjọ re tipẹ niti Shao Balẹ ni a n jẹ nibẹ tẹlẹ lati ọwọ Ikubabayeye.
Shao sunmọ sugbọn Ilọrin Afọnja dada lọjọ ti Laderin to tẹ Ilọrin n bọ lati Ọyọ Ọrọ (Ọyọ Ile) lẹgbẹ Jẹbba Shao losun.
Ilu Shao ti wa siwaju ilu Ilorin, ati Shao ati Jẹbba to fi mọ Ilọrin ilu Yoruba to tun jẹ Ilẹ Yoruba ti a si ti n sọ ede Yorùbá ni.